sÌse ojÚse wa nÍ nigeria nÍ ÌbÁmu pÈlÚ ÍlÀnÀ Òfin

8
SÌSE OJÚSE WA NÍ NIGERIA NÍ ÌBÁMU PÈLÚ ÍLÀNÀ ÒFIN ÌWÉ ÌLÉWÓ OJÚSE ENI NÍ ÌLÀNÀ ÒFIN

Upload: others

Post on 10-Nov-2021

6 views

Category:

Documents


0 download

TRANSCRIPT

Page 1: SÌSE OJÚSE WA NÍ NIGERIA NÍ ÌBÁMU PÈLÚ ÍLÀNÀ ÒFIN

SÌSE OJÚSE WA NÍ NIGERIA NÍ ÌBÁMU PÈLÚ ÍLÀNÀ ÒFINÌWÉ ÌLÉWÓ OJÚSE ENI NÍ ÌLÀNÀ ÒFIN

Page 2: SÌSE OJÚSE WA NÍ NIGERIA NÍ ÌBÁMU PÈLÚ ÍLÀNÀ ÒFIN

1

About BudgIT

BudgIT is a civic organisation driven to make the Nigerian budget and public data

more understandable and accessible across every literacy span.

BudgIT’s innovation within the public circle comes with a creative use of

government data by either presenting these in simple tweets, interactive formats

or infographic displays.

Our primary goal is to use creative technology to intersect civic engagement and

institutional reform.

Lead Partner : Oluseun Onigbinde

Research Team: Gabriel Okeowo, Ilevbaoje Uadamen and Adewole Adejola

Creative Development: Richard Ofunrein

Contact: [email protected] +234-803-727-6668, +234-908-333-1633

Address: 55, Moleye Street, Sabo, Yaba, Lagos, Nigeria.

© 2018

Disclaimer: This document has been produced by BudgIT to provide information

on budgets and public data issues. BudgIT hereby certi�es that all the views

expressed in this document accurately reflect our analytical views that we believe

are reliable and factbased.

Whilst reasonable care has been taken in preparing this document, no

responsibility or liability is accepted for errors or for any views expressed herein by

BudgIT for actions taken as a result of information provided in this Report.

ÌWÉ ÌLÉWÓ OJÚSE ENI NÍ ÌLÀNÀ ÒFIN

Kí ló dé tí o nfé ta ìbò re?

Njé Egbèrún Màrún Naira N5000 lè

bó ofún odún mérin?

#Ohuntiibokanto

Page 3: SÌSE OJÚSE WA NÍ NIGERIA NÍ ÌBÁMU PÈLÚ ÍLÀNÀ ÒFIN

mo-ilu je eni to ni awon ètó bii Omo orile-ede kan nitoripe a bii n'ibe tabi

Oboya nipa fifi òfin so o di Omo onilu; o si le tumo si enikan to ngbe

agbegbe kan. Ni ibamu pelu orile-ede, o le je omo-ilu ni orile-ede kan,

boya nipa wipe n'ibe ni won ti bi o, nipa isodomo labe ofin tabi nipa igbeyawo.

TAA NI OMO-ÌLU?

júse Omo-ilu je awon ohun ti eniyan to ngbe ni orílè-èdè kan nse fun

Oìdàgbàsókè orílè-èdè béè. Ìlú je ilé àjùmòtò fun awon asíwájú ati

omoléyìn, bee ni o je òrò-àgan - aláfowó-s'owópò-se fun gbogbo omo-

ilu, ko le maa tesiwaju. Ojúse lo je lati maa hù'wà tó tó ní ìbámu pelu ofin ati ilana ti

won fi n s'àkóso irúfé agbègbè bee. Omo-ilu gbodo je eni to setan lati fi ààyè sile

fun ohun tó tó lati selè, nitoripe bi irufe awon eniyan bayi ko ba fi ààyè sile fun ohun

to to lati sele, nkan ibaje a wa ni awujo, eyi si le se okùnfà ki awujo bee dàrú

pátápápá.

2

KÍ NI OJÚSE OMO-ÌLÚ?

ÌWÉ ÌLÉWÓ OJÚSE ENI NÍ ÌLÀNÀ ÒFIN

Page 4: SÌSE OJÚSE WA NÍ NIGERIA NÍ ÌBÁMU PÈLÚ ÍLÀNÀ ÒFIN

3

KÍ NI ÈTÓ ÀWON OMO ORÍLÈ-ÈDÈ NIGERIA?

Èto awon omo orile-ede po sugbon a o m'enu ba die ninu won. Gbogbo omo

orile-ede Nigeria lo ni:

po nkan ni a ni lati se ki a to le so wipe a je omo-ilu to nse ojuse re ni ona

Otó-tó. Ninu ìwé-ìléwó yi, a maa se alaye awon ohun mewa pataki to nje ki

eniyan di omo-ilu to nse ojuse re daadaa.

Sísan Owó-ìlú (owó-orí): Sisan owó-ìlú, ti a npe ni owó-orí télè, je ojúse omo-ilu.

Eyi je owo ti a nsan si apo ijoba, eleyi ti won nlo fun ipese awon ohun amáyéderùn

bii oju òpópónà to dara, ètò-èkó òfé, ati bee bee lo. Gbogbo omo-ilu to bá ns'ise

gbogbo san owó-ìlú, bee lo si je ètó omo-ilu lati beere bi won ti nna owo

naa.#BeereIbeere

AWON OJUSE MEWA TI A NI LATI SE KI A TO LE JE OMO-ILU TO NSE ÓHUN TÓ-TÓ

Ètó sí ìgbé-ayé;

Ètó sí ì-fún-n'íyì;

Ètó sí àsírí-ara-eni;

Ètó sí òmìnira-ara-eni;

Ètó sí ìtétísí-láìs'ègbè;

Ètó lati le dá-r'onú fúnra-eni, èrí-okàn ati èsín to wu ni;

Ètó sí òmìnira ìfé okàn eni;

Ètó òmìnira awon on'ísé ìròyìn;

Ètó sí awon àlàyé-òrò tó bá rú ni lójú;

Ètó lati se egbé tó bá wu ni;

Ètó lati se àpéjopò, ìwóde, sí-sé-ilé-isé-pa ati ìfèhónúhàn;

Ètó Òsèlú;

Ètó lati rìn s'íbi tó wuni ati lati gbé ibi tó wuni;

Ètó sí ètò orò-ajé ati awon ohun amáyéderùn bii ètò-ìlera, ilé-ìgbé, oúnje, omi, ààbò-ìlú ati

ÌWÉ ÌLÉWÓ OJÚSE ENI NÍ ÌLÀNÀ ÒFIN

Page 5: SÌSE OJÚSE WA NÍ NIGERIA NÍ ÌBÁMU PÈLÚ ÍLÀNÀ ÒFIN

Bèèrè Ìbéèrè: Gege bi omo-ìlú, a gbodo beers ibeere. Ona yi ni ona kan soso ti a le

fi mo awon igbese ti a le gbe bi enikan abi ni alajumose.

Fi Orúko s'ìlé lati d'Ìbò: Gbogbo orile-ede lo ni ojó-orí to ni ètó lati d'ibo. Ni Nigeria,

gbogbo omo-ilu to bá ti to omo odún méjìdínlógún lo ni ètó lati d'ibo.Ojuse ni eyi je

labe ofin lati ni asojú ninu ijoba, eleyi si se pataki fun ìgbéláruge agbègbè.

Ìfiokàtán: Gbogbo orile-ede lo nilo okan aisetan si ilu eni lati odo awon omo-ilu

bee. Gege bi omo-ilu, ko gbodo si ain'ife orile-ede eni lokan eni. Omo-ilu gbodo ni

fi owósowópò pelu awon agbofinro lati le gb'ogun ti iwa òdaràn láwùjo.

Je Òpágun fun Ìwé-òfin: Ìwé-òfin ni ohun-àkosílè to se pataki julo fun orile-ede,

gbogbo omo-ilu lo gbodo ni ìbòwò fun ofin orile-ede laisi awuyewuye tabi èrónú.

Mo Ètó Re: Gbogbo ètó ati ojúse gbogbo omo-ilu lo wa ninu Ìwé-òfin. Gbogbo

omo-ilu gbodo Mo ètó won ki won si se tan lati #BeereIbeere ti won bá fi eyikeyi

ninu ètó yi du won.

Mo ki o si maa ni Ìbásopò pelu awon Asojú re ninu Ìjoba: Omo-ilu gbodo mo asoju

agbegbe-idibo re ni Ilé-Ìgbìmò-Asòfin. Omo-ilu gbodo maa ni ìfikùlukùn pelu asoju

yi ni oore-koore nibi ipade inu gbògàn-ìlú, ko maa beere èkúnréré àlàyé lori awon

isé àkànse agbègbè ìdìbò, ko si pe fun sisoju eni bó ti tó nipa awon àbá.

B'òwò fun Ètó Omo-ìlú Miran: Ko si iyasoto ninu ètó enikan si enikeji bi a bá ns'oro

nipa ètó omo-ilu, ogboogba ni gbogbo omo-ilu loju ofin. Ètó lo je labe òfin ki a

bòwò fun ètó elomiran, ki a rii daju wipe òfin ati ààtò fi esè múlè, nitoripe eleyi lo

maa je ki a ni enu lati beere èrè oselu awarawa lowo ijoba.

Kopa Ninu Ohun to nlo ni Agbègbè re: Jíjé omo-ilu npe fun síse ojúse. Gege bi

omo-ilu, a gbodo mo wipe, bi o se je wipe apapo awon molebi lo ndi agbègbè, bee

naa lo je agbègbè ti a ko papo la npe ìlú, ti akopapo ìlú si je ohun ti a npe ni orile-

ede. Lara ohun ti a fi nda si oro agbègbè wa ni awon ohun to nmu idagbasoke bá

ilu bii fífarajìn, bíbuwólu ìwé-èhónú, ìbò dídì, didarapo pelu awon egbe to npe fun

sise ohun tó tó lawujo, ati bee bee lo.

4 ÌWÉ ÌLÉWÓ OJÚSE ENI NÍ ÌLÀNÀ ÒFIN

Page 6: SÌSE OJÚSE WA NÍ NIGERIA NÍ ÌBÁMU PÈLÚ ÍLÀNÀ ÒFIN

B'òwò fun Òfin Ijoba-Apapo, ti Ipinle ati ti Ibile: Gege bi omo-ilu, dandan ni fun wa

lati maa bu òwò fun awon òfin wonyi, ki a ma maa hu iwa lo lodi si àse-ìlú. Iwa to lodi

si àse-ìlú ni sise awon nkan to lodi si ase ijoba ati kíkòjálè lati tè lé awon ofin ilu kan,

ati/tabi ìpè, ìkìlò ati àse ijoba, tabi ti eni to wa nipo ase agbaye bee. Iwa to lodi si

ase-ilu kii saaba mu iwa idaluru dani.

TAA NI OLÚBORÍ AGBÈGBÈ?

Omo-ilu to bá n'ife lati fi t'inú-t'inú fi àkókò re sile lati ni ifikulukun pelu awon omo-

ilu elegbe re asoyepo/igbese lori ohun to je ètó won, to nse iranlowo tó tó fun won

lati mo ohun ti won ko mo to maa je ki won le darapo pelu ise-ilu, to si nfun won ni

atileyin lati maa beere ìsirò isé-ìríjú ati ifitonileti agbeyewo ibi-a-ba'se-de lowo

awon asoju won ninu ijoba, ki won le maa ni opo ohun amáyéderùn ni agbègbè

won.

Agbekale Ètò Olúborí-Agbègbè ni ajo to wa fun mimu ijoba sunmo ara ilu nipa sise

ilana awon ètò ìlanilóyè fun awon eniyan kaakiri ìletò ati ilu nla-nla lati sí won ní iyè

lati maa beere ìsirò isé-ìríjú ati agbeyewo ibi-a-ba'se-de lowo awon ti a d'ibo yan

gege bi asoju wa ninu ijoba, ki ìwúrì le wa fun won lati le maa se ojuse won ni ilu,

iyen àjo BudgIT, da sile. Ori èro-ayélujára ni ajo yi ti nse awon ètò wonyi lori awon

ojú-òpó ayélujára wonyi: www.yourbudgit.com ati www.tracka.ng pelu kókóró òro

alásopò ti #GetInvolved.

OHUN TI OLÚBORÍ-AGBÈGBÈ NSE

Olúborí-Agbègbè maa nni ìfikùnlukùn pelu awon olugbe agbègbè won lori

idanileko ètò-ìsèlú ati awon awon ohun to nii se pelu ètò-ìsúná, ti won si nfi

abajade iwadi won ranse si awon osise Tracka.

Nipase ekunrere ètò-ìsúná ninu ìwé-ìléwó, Olúborí-Agbègbè ns'eto

ìlanilóye ati atileyin fun awon olugbe agbègbè won lati gba awon isé-àkànse

agbègbè-ìdìbò won gege bii nkan ìní won.

5 ÌWÉ ÌLÉWÓ OJÚSE ENI NÍ ÌLÀNÀ ÒFIN

Page 7: SÌSE OJÚSE WA NÍ NIGERIA NÍ ÌBÁMU PÈLÚ ÍLÀNÀ ÒFIN

Ni osoosu ni Olúborí-Agbègbè maa nni ipade po pelu awon òsìsé won ti won

ntopinpin awon isé-àkànse agbègbè-ìdìbò lati se eto ipade inu gbògàn-ilu

pelu awon eniyan kaakiri agbègbè ti awon ise-akanse won bá wa ninu ètò-

ìsúná.

Olúborí-Agbègbè je alárinà laarin awon osise atopinpin ati awon agbègbè

won bi a bá ns'oro nipa ifikunlukun lagbègbè.

OHUN TI O GBODO SE BAYI!!!

Mo nkan: Mo awon isé-àkànse ijoba ni agbègbè re

(kan si ori èro ayélujára www.yourbudgit.com).

Gbe igbese: Lo si awon ibiti awon isé-àkànse yi wa

fun itopinpin won.

Fikúnlukún: Bá awon asojú ti e d'ibo yan si ile-igbimo asofin ipinle ati ti àpapò sòròpò. Bee naa lo le ko awon eniyan jo ni agbègbè re lati jijo ko iwe si asoyin yin.

Ko iwe pelu atileyin ofin Anfaani si Àlàyé: ko iwe si ile-ise/àjo ijoba ti isé-àkànse naa wa ni ìkáwó re lati beere fun alaye ibi ti ise nlo ati ibiti ise de nipa isé-àkànse naa.

So Fún Wa: Je ki a mo abajade iwadi re nipa

ifitonileti lori èro ayélujára ti www.tracka.ng

Agbègbè re nilo re. Iwo ni Olúborí ti o maa mu ayipada ba agbègbè re.Di Olúborí-Agbègbè loni. Fi àtèránsé ori èro ayélujára ranse si: [email protected] tabi ki o pe wa s'ori: +234-803-727-66

NOTE

12345

6 ÌWÉ ÌLÉWÓ OJÚSE ENI NÍ ÌLÀNÀ ÒFIN

Page 8: SÌSE OJÚSE WA NÍ NIGERIA NÍ ÌBÁMU PÈLÚ ÍLÀNÀ ÒFIN

www.tracka.ng @trackaNG [email protected]